Jẹ́ ki a ki Eṣu Ẹlẹ́gbára

 


 

Ẹ kú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ èdè ati Àà Yorùbá.

Orúkọ mi ni Ọ̀mọ̀ Adelson Adéwalé de Brito ti ọpọlọ́pọ̀ ènìyàn mọ̀ Mọ̀wé Adelson tabi Mawo Adelson.

Olori ẹ̀sín ibilẹ̀ Vodun ti àwn alale wa mú lati iha oòrùn ilẹ̀ aláwọ̀ si ilẹ̀ Amẹ́rika iakoko òwò ẹrú, ni mi.

Ọmọ orílẹ̀ede Brasili ni mi, ṣùgbọ́n, Mo yangan pe iran Ànàgó ni mi. Emi jẹ́ ara ipelẹ̀ akoko ninu iran Ànàgó ti wọn mu wa si orílẹ̀ede yìí laarin ni ọgọ́run mẹ́ta ọdún sẹ́hìn, lasiko òwò ẹrú.

Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé Olódùmarè ló rán ifá wá láti òde ọ̀run latí wá fi ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé ṣe.

Ni aye atijọ́, àwọn àgbààgbà Ànàgó lò s wi pé kí ó tó bèrè ld Ifá, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé bèrè àyè latd Eu Ẹlẹ́gbára.... 

Ẹ́ jẹ́ ki a ki Eu Ẹlẹ́gbára

Èṣù Láàlú

Ogiri okó

Laroye àroógọ

Abániwọràn báòrídá

Ẹbọra tííjẹ Látọpa

Èṣù Ọdàrà onilé orita

Agọgọlágọ, agọgọlágọ

Alàmọnlamọn bàtá

Ofẹ bàtákú jó lamulámú

Ọkùnrin firi firi firi já pi!

Ọkùnrin fìrì fìrì fìrì já pi!

Ọkùnrin bàà bàà bàà bi ẹbáko

Jagunlabí nlọ láàrin ẹpà,

Ààsóorí ẹ fééé!

Woni ọpẹlopẹ giga ti Látọpaga

Èṣù Láàlú

Ogiri oko

Ọbẹlẹkún sunkún kẹru ó bẹlẹkún

Ẹlẹkún sunkún

Láaróyè nsùnjẹ

Èṣù Ọdàrà má bámijà

Ng ò lowó ẹbọ nilé!

Oorò Èṣù! Oorò Èṣù! Oorò Èṣù!

Láàlú, bàbá májẹ nrẹjọ!

Láàlú, bàbá májẹ nrẹjọ!

Láàlú, bàbá májẹ nrẹjọ! 

Ifá jẹ́ èto nla nipa ọ̀na olukaluku ènìyàn lára igbesiaye rẹ̀ ninu 

Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé Olódùmarè ló rán ifá wá láti òde ọ̀run latí wá fi ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé ṣe. Ọgbọ́n, ìmọ̀, àti òye tí Olódùmarè fi fún Ifá ló fún Ifá ní ipò ńlá láàárín àwọn ìbọ ní ilẹ̀ Yorùbá. “A-kéré-finú-ṣọgbọ́n” ni oríkì ifá.

Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni wípé ní ìgbà kan rí, ifá gbé òde-ayé fún ìgbà pípẹ́ kí o tó padà lọ sí ọ̀rùn. Ní ìgbà tí ifá fi wà ní ilé ayé, ó gbé ilé-ifẹ̀ fún ìgbà péréte. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí ọ̀rúnmìlà fi wà láyé yìí náà, a tún máa lọ sí òde ọ̀run lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí olódùmarè bá pèé láti wá fi ọgbọ́n rẹ̀ bá òun tún òde-ọ̀rùn ṣe. Nítorí náà gbáyégbọ́run ni ifá ńṣe.


Comentários